9ice – Olódùmarè Lyrics

Olódùmarè Lyrics By 9ice

Olódùmarè Lyrics
Olódùmarè Lyrics
  • Artist 9ice
  • Title Olódùmarè
  • Album Beginning of Wisdom (Bow)

Ẹ̀mí kan, ẹ̀dá kan
Ayé kan ló wà
Ẹ̀mí kan, ẹ̀dá kan
Ayé kan ló wà
Ah ah
Tí n bá ń lọ lọ́nà màá ko ire
Àbọ̀ mi ma ń da ire
Gbogbo ìrìn tí mo bá ń rìn ma ń d’oore
Gbogbo iṣẹ́ tí mo bá ń ṣe ló ma ń d’ọpẹ́
Tí n bá ń bọ̀ ní ibìkan
Tí n lọ sí ibìkan màá gba ire
Tí mo yà sí ibì kan ma gb’ọpẹ́
Ọ̀nà mi ma ń fọ ire
Olódùmarè ló jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀
Ṣe ni mo ya ma ń dákẹ́ ṣ’ọpẹ́
Olódùmarè olórí
Olódùmarè adarí
Olódùmarè mare
Olódùmarè marè
Ṣèbí ìwọ ni adákẹ́jà bí idán
Ajàbí-èpè bí àrá o
Bàbá bàbá ah
Ṣe mí lóore àṣepé
Ṣàánú ọmọ ọ̀ rẹ
Bàbá mi
Bàbá bàbá ah
Má dáwọ́ oore è rẹ dúró
Ṣàánú ọmọ'ọ̀ rẹ
Ìyà ò lè jẹ mí torí mi ò p’awo dà
Ọ̀kanlọmọ (Anaconda)
Colour media (Cosatira)
Hallelujah (Wọ́n á rí wonder)
Mo ní Badmus ọ̀nà wa á là
Tí n bá ń lọ lọ́nà màá ko ire
Àbọ̀ mi ma ń da ire
Gbogbo ìrìn tí mo bá ń rìn ma ń d’oore
Gbogbo iṣẹ́ tí mo bá ń ṣe ló ma ń d’ọpẹ́
Tí n bá ń bọ̀ ní ibìkan
Tí n lọ sí ibìkan màá gba ire
Tí mo yà sí ibì kan ma gb’ọpẹ́
Ọ̀nà mi ma ń fọ ire
Olódùmarè ló jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀
Ṣe ni mo ya ma ń dákẹ́ ṣ’ọpẹ́
Olódùmarè olórí
Olódùmarè adarí
Olódùmarè mare
Olódùmarè marè
Ṣèbí ìwọ ni adákẹ́jà bí idán
Bí I Ogbèríkúsá, it's just by the way
Ẹ b'Ọlọ́run ní bẹ́ẹ̀, ẹ ò le bá mi ṣá
It's just by His Grace
I shall never fall
Ìyà ò lè jẹ mí torí mi ò p’awo dà
Ọ̀kanlọmọ (Anaconda)
Colour media (Cosatira)
Hallelujah (Wọ́n á rí wonder)
Mo ní Badmus ọ̀nà wa á là
Ṣe mí lóore àṣepé
Ṣe mí lóore àṣepé
Ṣàánú ọmọ ọ̀ rẹ
Ṣe mí lóore àṣepé
Ṣe mí lóore àṣepé
Ṣàánú ọmọ ọ̀ rẹ
Ṣe mí lóore àṣepé
Ṣe mí lóore àṣepé
Ṣàánú ọmọ ọ̀ rẹ
It's Bizzle on the mix

READ ALSO  Birdman & Lil Wayne – Out the Pound Lyrics

Leave A Comment