Sola Allyson – Alujanjankijan (feat. Adekunle Gold) Lyrics

Alujanjankijan Lyrics By Sola Allyson

Alujanjankijan Lyrics
Alujanjankijan Lyrics
  • Artist Sola Allyson
  • Featured Adekunle Gold
  • Title Alujanjankijan
  • Album Alujanjankijan (feat. Adekunle Gold) – Single

Iya, Iya takun walẹ (Alujanjankijan)
Iya, Iya takun walẹ (Alujanjankijan)
Ẹ ma fọmọ silẹ fun'ya jẹ (Alujanjankijan)
Ẹni to bimọ lo yẹ ko w'ọmọ (Alujanjankijan)
Ba mi n'ọmọ mi, o yẹ ko denu ọlọmọ
Oju mẹrin lo n bimọ ṣugbọn, igba oju ni n w'ọmọ
Ọmọ ta o ko, a gbele ta kọ ta
Ọmọ ta o tọ, a kẹṣọọ ta ni ta
Ọmọ nigbẹyin, ọmọ lọla, ọmọ lọla, ọmọ niyi, ọmọ lade
Ọmọ lẹwa, ọmọ lẹṣọọ oh ohhh
O da a, bi o da a- o le da a; o san, bi o san- a dẹ san
Igboya at'adura ni o gba- yi o da ahhh
Iya, Iya takun walẹ (Alujanjankijan)
Iya, Iya takun walẹ (Alujanjankijan)
Ẹ ma fọmọ silẹ fun'ya jẹ (Alujanjankijan)
Ẹni to bimọ lo yẹ ko w'ọmọ ẹ, ẹ tọmọ (Alujanjankijan)
Ori fun wa l'ọmọ're bi i ti Samuel oh
Wọn kọ Saamu, o gbẹkọ oh, o si ṣehun rere
If you spare the rod, you go spoil the child; I hope you know?
Train them with the love of God; abegi oh
Tori, alaigbọran ọmọ (Aṣa ni)
Agba o kunwọ l'oju (Aṣa ni)
Agba o jọ wọn loju oh (Aṣa ni)
Agba iya ni o da (Aṣa ni)
Alalugbọran ọmọ oh (Ọmọ ni)
Wọn le d'eyan lọla (Ọmọ ni)
Ta ba tọ wọn daada o (Ọmọ ni)
Wọn le d'eyan lọla
Iya, Iya takun walẹ (Alujanjankijan)
Iya, Iya takun walẹ (Alujanjankijan)
Ẹni to bimọ lo yẹ ko w'ọmọ ẹ (Alujanjankijan)
Ẹ ma fọmọ silẹ fun'ya jẹ (Alujanjankijan)
Iya, Iya takun walẹ oh (Alujanjankijan)
E ma fọmọ silẹ fun'ya jẹ (Alujanjankijan)
Ẹni to bimọ ẹ lo yẹ ko w'ọmọ ẹ, ẹ tọmọ (Alujanjankijan)
Iya, baba, takun walẹ (Alujanjankijan)
Kekere la ti n pẹka Iroko to ba dagba tan ẹbọ ni yoo maa gba
Ohun ta ba fi silẹ l'ewurẹ gbe, k'ewurẹ aye ma ma gbe wa lọmọ lọ
Ọmọ ta o ba tọ ẹkun aye a gbe lọ, k'ẹkun aye ma ma gbe wa lọmọ lọ
Iya, Iya takun walẹ oh oh (Alujanjankijan)
Iya, Iya takun walẹ oh oh (Alujanjankijan)
Iya, Iya takun (Alujanjankijan)
Iya, Iya takun walẹ oh oh (Alujanjankijan)
Edumare ko ba wa ṣọmọ wa o
Edumare ko ba wa tọmọ wa o
Train them with the love of the God o
Ẹ gbọ, ọmọ lọla, ọmọ lade, ọmọ lẹwa, ọmọ lere
Ka faye silẹ ka tọmọ wa o (Alujanjankijan)
They are the future generation (Alujanjankijan)
Iya, Iya takun walẹ oh (Alujanjankijan)

READ ALSO  Adekunle Gold – Sunday (Apple Music Home Session) Lyrics

Leave A Comment